Ajo eso asobode ipinle Ogun gba lresi,taya moto, ati igbo pelu ibon lowo awon onifayawo.

Kontirola Muhammed Shuaibu to n dari ajo eso asobode akoko nipinle ogun ti fi awon eru ti won gba laarin osu meta akoko ninu odun egbaa odun o-le marunlelogun yi han awon oniroyin ni ofisi re to wa ni idiroko .
Shuaibu ni aropo gbogbo owo ori awon eru fayawo ti won gba laarin osu meta akoko naa je #314,057,716 milionu .
Be lo je ko di mimo pe awon gba awon eru naa ni opopona ilaro si Abeokuta, lpokia si Idiroko .
Lara awon eru fayawo ti won gba naa ni Ibon meta, ti onifayawo kan di sinu apo to si ko eepo iki sii pelu ota ibo ogorun.
Awon nnkan mii ti won tun gba ni : Aloku aso, lgbo ,epo Bentiro egberun metala lita.
Won tun gba moto Tokunbo meta ,paali Amoxicillin capsules, Suga,filawa ati POP cement pelu ose iwe ti won ko wole lati orileede Ghana.
Muhammed ni ise asekara tawon osise naa n se pelu ifowosowopo awon ajo eleto aabo to ku lo ran awon lowo lati saseyori nidi ise naa.
“laarin osu meta ti mo lo mo sise kara lati lo sodo awon olori ilu ati awon odo .
Leyin iyen mo lo si odo awon asobode akegbe wa lorileede olominira Benni ninu osu keta odun yi”.
‘A soro lori bo se ye ki awon eeyan se ma se owo ni Golo lai tako ofin Naijiria.
Mo lo sodo adari won ni Porti novo a si soro lori awon adojuko ti a ni ,mo lero pe aseyori yi ma jade laipe.
Niti iyato to wa ninu owo ori ti ajo naa pa wole laarin osu meta odun 2024 si 2025 o je 7.6 milionu ni owo ori taa pa lasiko yi fi ju ti odun to koja lo.
Ogbeni Adeyeye olusegun to je adari ajo NDLEA Idiroko to tewo gba awon esibiti naa lowo kontirola Shuaibu ro awon obi lati ma sakiyesi won daadaa ki won ma ba ma mu ipo ” igbo mimu ma n ba ojo ola awon eeyan je ni”.
Eto kan ti a fi odiidi ose kan se to da lori bi a se ma se owo lona eto ni a ti ko awon akeko, onise owo ati awon eeyan lawon bi won se n se owo lona to ba eto mu.
Mo n fi asiko yi ro awon eeyan lati yera fun ise fayawo tori o n ba eto oro aje orileede wa je.
Be ni mo n ro awon eeyan lati fowosowopo pelu wa lati gbogun ti awon onifayawo.
Mo n fi dayin loju pe a o ni kere lati ma gbogun ti awon to n se ise fayawo .




