Eso aṣọ́bodè gba Oko Range Rover 2026, ati awon eru fayawo ti Owo Ori re je N2.5bn laarin ose marun pere.

Ilé iṣẹ́ Aṣọ́bodè Nàìjíríà eka akoko ni ipinle ogun ti kéde awon eru fayawo ti won gbà lowo awon onifayawo laarin ose marun pere fawon Oniroyin.
Lara awon eru fayawo naa la ti ri ọkọ̀ Range Rover Sport 2026 àti àwọn ọjà mii ti aropo Owo Ori (DPV) re jẹ́ N2.47 billion láàárín ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kẹjọ sí ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù kẹsàn-án odun Egbaa odun o-le marundinlogbon .
Olùdarí Agbègbè náà, Igbákejì Olùdarí Oladapo Afeni, ló sọ èyí níbi ìpàdé àwọn oníròyìn ní ọjọ́rú ní Idiroko.
Afeni sọ pe awọn gbà awon eru naa lowo awon onifayawo jakejado ipinle ogun. Be lo je ko di mimo pe ajo naa ko kere lati ma se ayewo awon eru ti won n ko wole jade ni orileede Naijiria fin-ni fin-ni.
Afeni wa menuba iye awon eru ti won gba leyo kookan láàárín ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kẹjọ sí ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù kẹsàn-án .
Won gbà iresi ilẹ̀ òkèèrè tó tó egberun kan igba ole merin (1,204), ìdìpọ̀ Igbo cannabis indic egberun meta ole (3,893), àwọn ègé 428 ti pneumatic taya àti 8,675 jaala Epo Bentiro .
Àwọn mìíràn ni aṣọ àlòku mẹ́rìnlélógún, bàtà ìgbàlódé mẹ́rin àti egberun marun 500 jaala Epo disu.
Aropo gbogbo Owo Ori DPV awon eru naa je Bilionu meji ole, N2,469,153,523.68.
Afeni sapejuwe oko Range Rover Sport Autobiography P530 ti ọdun 2026, ti Owo Ori re jẹ N417.01 milionu ti won gbà gege bi Aseyori nla ti Ile ise naa se lati dekun awon onifayawo to Fe ma se akoba fun eto oro aje orileede Naijiria.
Ó tún sọ pé àwọn aláṣẹ náà yóò máa dáàbò bo àwọn àǹfààní ọrọ̀ ajé Nàìjíríà àti ààbò orílẹ̀-èdè.
Olùdarí náà kìlọ̀ fún àwọn tó ń ṣe akoba fun eto ọrọ̀ ajé àti àwọn ìgbòkègbodò ààlà tí kò bófin mu láti jáwọ́ nínú irú àwọn ìwà bẹ́ẹ̀, ó ní awon eso Asobode ko ni kere lati ma gbogun ti iru awon to won na yan ise naa laayo.



